Tambuwal ké gbàjarè lórí Covid 19 ní Sokoto


Fẹ́mi Akínṣọlá

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bá a se ń  pà kan, lòmíì
Gómìnà Aminu Tambuwal tó ń tukọ̀ Ìpínlẹ Sokoto ti ke gbàjarè síta lórí iye àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ rẹ̀ tó ń lùgbàdi àjàkálẹ̀ àrùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì báyìí.

Ó ní láti ọjọ́ Àìkú ni wọ́n ti ń lé síi ní èyí tó n kọ òun lóminú.

Báyìí, ó ti kéde òfin kónílé-ó-gbélé láti aago mẹ́jọ sí aago mẹ́fà ìdájí.

Bákan náà ló tún rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti túbọ̀ ní ìmọ́tótó dáadáa lásìkò yìí pẹ̀lú títa kété síra ẹni

Tambuwal rọ ìjọba àpapọ̀ láti dìde sí ìrànlọ́wọ́ Sokoto lórí ohun èèlò àyẹ̀wò, ki ìtànkálẹ̀ àrùn náà le dínkù.

Báyìí, ó ti di èèyàn mẹ́rìndínláàdọ́rin   tó ti ní àrùn apinni léèmí Kofi 19.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé