Owó Abacha kú, $319m ní UK àti France - Amẹ́ríkàFẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tún ti sísọ lójú rẹ pé, owó tó tó okòólélọ́ọ̀dúnrún ó dín kan dọ́là ($319m), owó tí Abacha jí kó pamọ́ sí ìlú ọba, UK àti Faransé sì tún wà nílẹ̀.

Àtẹjáde kan tí iléeṣẹ́ aṣojú ìjọba Amẹ́ríkà fisíta ní Ọjọ́rú ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àfikún pé, ọgọ́jọ mílíọ̀nù àti méje dọ́là ($167m) ni Abacha kó pamọ́ sí ilẹ̀ Faransé nígbà tí mílíọ̀nù méjìléláàdọ́jọ dọ́là ($152m) míràn tún wà ní ilẹ̀ UK, tí wọ́n sì ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́.

Àtẹjáde náà ní owó tuntun yìí, tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ bílíọ̀nù lọ́nà méjìdínlọ́gọ́fà náírà, (N118bn) tún yàtọ̀ sí àádọ́sàn mílíọ̀nù dọ́là ó dín mẹ́ta ($167m) tí ìjọba ilẹ̀ UK àti Faransé gbé  ẹsẹ̀ lé, tó fi mọ́ mílíọ̀nù méjìléláàdọ́jọ dọ́là ($152m) míràn tí wọ́n ń bá ìjọba UK ṣe ẹjọ́ lé lórí.

Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, ìjọba Nàìjíríà tí gbé ilẹ UK lọ sile ẹjọ́ láti gba àwọn owó náà, kò tó ko ìdá àádọ́rin fún Atiku Bagudu, tíì ṣe alájọ sisẹ́pọ̀ Sani Abacha, tí àdéhùn jọ wà láàrin òun àti ìjọba Nàìjíríà nípa owó náà

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

“MERCY” by Bisi Adeleye-Fayemi

Ekiti Deputy Speaker hails Muslims on Eid-el-fitr celebration