Ọ̀pọ̀ ló ń f'òjò p'òjó Emir tó wájà


Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kò kúkú sẹ́ni tí kò ní kú, kò sèèyan t'óko  baba rẹ̀ kò ní ìgboro. Gbogbo ẹ̀dà ló wọ agbádá ikú , ká má wulẹ̀ fikú yọ ra a wa.
Èyí lọrọ tó gba ẹnu àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kano kan báyìí ní bí ìràwọ̀ ńlá kan láti ààfin ìlú náà se já lójijì.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta yìí ni Emir Rano tí ìpínlẹ̀ Kano dágbére fayé pé ó dìgbà, nílé ìwòsàn Nasarawa General Hospital ní Kano.

Alhaji Tafida Abubakar papòdà lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́rin.

Kabiru Alhassan Rurum tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ aṣojú ilé Ọba Rano àti Bunkure àti Ranon Wali Ado tó jẹ́ agbẹnusọ ṣàlàyé pé nǹkan bíi ọjọ́ márùn ún sẹ́yìn ló ti rẹ Emir kí wọ́n tó gbé e lọ sílé ìwòsàn ní ọjọ́ Ẹtì.

Emir yìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn Emir mẹ́rin tí Gómìnà Ganduje yàn lá'ti fi pín ìtẹ́ Emir Sanusi ti Kano ní ọdún tó kọjá, kó tó di pé wọ́n rọ Lamido Sanusi lóyè emir lọ́dún yìí

Wali Ado ni Emir Rano ti ní ẹ̀jẹ̀ ríru àti ìtọ̀ ọ ṣúgà tó ń bá fínra tẹ́lẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó kànkùn.

Wọ́n ní Emir fi aya méjì àti ọmọ mẹ́tàdínlógún sílẹ̀ lọ.

Ọkùnrin méjìlá àti obìnrin márùn ún ló selédè Emir Rano.

Kí Ọlọ́run foríjin  òkú ni àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí wọ́n se ń dárò  nílùú Kano báyìí.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé