Ọọ̀nirìṣà Ọba Ògúnwùsì f'ògún ẹ̀ gbárí, òògùn ìbílẹ̀ lè wo Kofi-19Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní, dán an wò, ló bí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́, àti pé bí ògún ẹni bá dáni lójú, a fi í gbá àtàrí ní ló mú kí àwọn àgbà kan, àgbà kàn nílẹ̀ yìí o jẹ́ á mọ́ pé  a ní nǹkan tó àmúyẹ lábẹ́lé to se é kójú  àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi 19 tó ń mi gbogbo àgbáláayé lògbòlògbò.
Láìpẹ́ yìí ni Mínísítà fún ètò ìlera ní Nàìjíríà, Dókítà Osagie Ehanire kéde pé, ìjọba kò tako àmúlò òògùn ìbílẹ̀ fún ìwòsàn àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ Kofi 19.

Àrùn aṣekú pani ọ̀hún, sì ni àbíkú rẹ̀ ti sọ àwọn oníṣègùn jákèjádò àgbáyé di èké, tí wọ́n sì ní àwọn kò rí ìwòsàn fún àjàkálẹ̀ àrùn Kofi -19 náà.

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé, àwọn ibi táa fi ojú sí l'ágbàáyé lórí wíwá ìwòsàn fún àrùn yìí, ọ̀nà kò gba ibẹ̀ lọ, lo mú kí àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan dìde láti wá ìwòsàn pẹ̀lú oògùn ìbílẹ̀.

Orílẹ̀ èdè Áfíríkà bíi Madagascar Cameroon àti Nàìjíríà sì ti ń fi  ògún rẹ̀ gbárí pé, àwọn òògùn ìbílẹ̀ kan leè wo àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì, tí Madagascar sì ti ń lo òògùn ìbílẹ̀ tiẹ̀ fún ìwòsàn àrùn náà.

Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, àwọn ọba alayé bíi Ọọ̀ni tìlú Ilé-Ifẹ̀, Ọba Adéyẹyè Enitan Ògúnwùsì,  Ọ̀jájá Kejì àti Aláàfin tilu Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta, tó fi mọ òjíṣẹ́ Ọlọ́run bíi Fada Anselm Adodo àti oníṣẹ́ ìwádìí Ìṣègùn bíi Ọ̀jọ̀gbọ́n Maurice Iwu, ló fi ọwọ́ gbá àyà pé, òògùn ìbílẹ̀ yóò ṣe ìwòsàn àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún,Kofi 19.

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

FAYEMI CONGRATULATES EX-DEPUTY GOVERNOR, ADELABU ON 70TH BIRTHDAY

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀