Ọlọ́pàá wú òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Uniport t'àwọn ajínigbé sinFẹ́mi Akínṣọlá


Ìwé mímọ́ ní bí òpin ayé bá ń bọ̀, onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà la ó máa rí, bẹ́ẹ̀ ìtìjú yóó káṣẹ̀ ń lẹ̀ pátápáta, ìwà a kò tọ́ ó sì padà d'ohun àmúyagàn lójú ọmọ àráyé.
 Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Rivers ti wú òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì ìlú Port Harcourt mẹ́ta jáde lọ́jọ́ Ẹtì: méjì jẹ́ ọkùnrin, ẹnìkan sì jẹ́ obìnrin.

Ọjọ́ keje, oṣù Kẹrin, ọdún 2020 ni àwọn ajínigbé gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, Nelson Nwafor, Fortune Obemba àti Joy Adoki, nílù Choba tó jẹ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó yí Fásitì náà ká. Ṣùgbọ́n ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí mẹ́ta ní ọgbọ̀ńjọ́, oṣù Kẹrin, ọdún 2020, gẹ́gẹ́ bí nǹkan tí wọ́n sọ fún akọ̀ròyìn.

Ọ̀kan lára àwọn afurasí tọ́wọ́ tẹ̀, Friday Akpan, ló mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibi tí wọ́n ti wú àwọn òkú náà jáde nínú ibojì kótópó kan tí wọ́n sin wọ́n sí nínú igbó ládùgbóò Eleme, lọ́jọ́ kínní, oṣù Karùn ún, ọdún 2020

Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe sọ, Akpan jẹ́wọ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn ni òun, àwọn sì ti jí àwọn èèyàn gbé lẹ́ẹ̀mejì.

Akpan sọ pé ọ̀kan lára àwọn adarí ẹgbẹ́ náà, Bright, ló jí àwọn akẹkọọ tó ti d'olóògbé "nítorí pé ọ̀kan lára wọn dalẹ òun lásìkò tí owó kan wọ àkáǹtì rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó kọ̀,l láti kó o sílẹ̀ f'óun".

Èyí ló mú kó ránṣẹ́ pe Akpan àti àwọn yókù rẹ̀ láti gbé wọn lọ̀ ọ́ pa sínú igbó.

Akpan sọ fún àwọn ọlọ́pàá pé Bright ló pàṣẹ pé kí wọ́n ó gbẹ́mì lẹ́nu wọ́n.

Kọmísánà fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ náà, Joseph Mukan sọ pé kí àwọn ẹbí àwọn olóògbé ó má fòyà, nítorí pé àwọn yóó rí i pé ìdájọ́ òdodo fẹsẹ̀múlẹ̀.

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

FAYEMI CONGRATULATES EX-DEPUTY GOVERNOR, ADELABU ON 70TH BIRTHDAY

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀