Òfin kónílé-ó-gbélé kọjú oro sáwọn kọ̀lọ̀rànsí awakọ̀ ìlú Kano


Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti èèyàn ní òpópónà ìpínlẹ̀ Kano KAROTA ti ní àwọn kò ní fi ọwọ́  dẹngbẹrẹ mú ẹnikẹ́ni tó bá rú òfin kónílé-ó-gbélé ní àwọn àsìkò tí Ìjọba sọ ní Kano.Wọ́n ní ẹ̀sùn ìpànìyàn ni àwọn máa fi kan irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Baffa Dangaganda tó jẹ́ adarí ikọ̀ KAROTA sọ fún akọ̀ròyìn pé àwọn ti rí ọ̀nà kọ̀rọ̀ mẹ́tàdínlógún míràn yàtọ̀ sí àwọn márosẹ̀ ní èyí tí àwọn dírẹ́bà ń dọ́gbọ́n gbà lásìkò òfin ìṣéde yìí.

Ó ní ìjìyà tó tọ́ wà fún ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ pé ó rú òfin yìí.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé