Mo bọkú lọ́wọ́, Ọlọ́run Allah ló dá mi padà -- Mallam El Rufai


Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó hàn báyìí pé ọ̀rọ̀ kofiidi 19 yìí ti kúrò ní awẹ́wa o, bí Gómìnà Kàdúná Mallam El Rufai ṣe kẹnu bọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó jàjàbọ́ láìpẹ́ yìí lọ́wọ́ àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì tó ń mi gbogbo àgbáyé lògbòlògbò.
Ó ní àrùn náà kò wojú ẹnikẹ́ni ṣèjàǹbá o.
"Àánú ní mo rí gbà bí mo se tẹ̀lé àmọ̀ràn àwọn dókítà nílànà bí wọ́n se ní ń lòògùn lásìkò ìyaraẹni ṣọ́tọ̀, ìgbélé tipátipá ọ̀hún".

Ó ní ipa tó wàyàmì ní àwọn aya àti ìgbákejì rẹ̀ ,Omọ̀wé Hadiza kó bí wọ́n se fi ọgbọ́n inú gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ku ọ̀kan dondo tí o fí ń wo kínní ń ṣẹlẹ̀ lágbàáláayé, èyí tó sèrànwọ́ fún àlèékún àlàáfíà rẹ̀ lásìkò náà.

Gómìnà ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ò lè ṣọ pàtó ibi iná àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí gbà bọ́sí i lábẹ́ aṣọ, ó ní kò ṣé lẹ́yìn ìfarakínra rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn kan l'Abuja tí wọ́n wá látòkè òkun àti nílẹ̀ yìí, ìyẹn lásìkò iṣẹ́ ìlú tí ìjọba gbé lé e lọ́wọ́    níbi tó ti jẹ́ Alága ìgbìmọ̀.
Ó ní pẹ̀lú gbogbo bí ààbò ṣe yíipo, àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni ọ̀hún se kọ́sọ́ sí òun lára.

Ó ní àrùn náà máa ń fí àwọn  tó bá ń súnmọ́ ipò arúgbó torí pé òun tí lé ní ọmọ ọgọ́ta ọdún, àti pé  àrùn náà jowú  púpọ̀,bí ó bá fi se kòǹgẹ́ àrùn mìíràn lágọ̀ọ́ ẹni tó mú, àánú Ọlọ́run lonítọ̀ùn fi lé yàn an yọ.

"Mo mọ̀ọ́ lá a púpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀fọ́rí àbaàdì, n o le gbàdúrà rẹ̀ kí ó mú ọ̀tá a mi, ìdí nìyí tí a tún fí kógìírí mọ́ ọ.
Gómìnà El- Rufai ní mo firun àgbọ̀n mi se súnà ni, ṣùgbọ́n báyìí ná,mo tí fá a fún ìdí kan.

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

Fayemi Approves Ilomu, Otun Obas-Elect, Forwards Supplementary Budget to Assembly

Me, Adedubu, Alao-Akala And Obasanjo - By Rashidi Ladoja