Kọ̀lọ̀rànsí,ọ̀daràn ẹ bìlà, ìpínlẹ̀ Èkìtì á gbóná mọ́ ọn yin-- FáyẹmíFẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kójú o tó fọ́ la tií kìlọ̀ òkò.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì Ọ̀mọ̀wé Káyọ̀dé Fáyẹmí tí fìka tọ́lẹ̀ lá láti kọjú oro sí ìwà ọ̀daràn àti n tí ó fara pẹ́ ẹ ní ìlú náà.

Ṣé wọ́n ní kí ìlú ó tó tú ,lati í kìlọ̀ ìwà.
Àti pé èèyàn tó ja Ṣàngó lólè, ló ń wá Ìbínú òòsà.
Gómìnà Fáyemí ṣọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń gba Kọmíṣọ́nnà  fétò ọ̀gbìn, Ọ̀gbẹ́ni Folorunsho Olabode, tó ṣẹṣẹ gbòmìnira lọ́wọ́ àwọn kọ̀lọ̀rànsí ajínigbé, ẹni tí Alága ẹgbẹ́ onítẹ̀síwájú Ilejemeje ( APC) kọ́wọ̀ọ́rìn tẹ̀lé wá fi ẹ̀mì ìmoore hàn sí bí gómìnà se kógìírí mọ́ bí wọ́n se ṣàwárí i Kọmíṣọ́nnà náà.

Nígbà tó ń fìdùnú rẹ̀ hàn sí bí Kọmíṣọ́nnà se di rírí padà láàyè, ó ní , àì lásọ lọ́rùn un pààká, ó tó àpérò Maríwo. À kúkú ù joyè sàn ju ẹnu ùn mi ò ká ìlú.
Ó fọwọ́ gbáyà pé òun yóó túbọ̀ lékún ìfúnpinpin mọ́wà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ náà, bákan náà ló kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn èèyàn agbègbè Ilejemeje látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì tó mẹ́mìín aṣíwájú Ìjọba ìbílẹ̀ Ilejemeje tí ẹ̀mí rẹ̀ bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ lásìkò ìjínigbé ọ̀hún.

Ó ní ìjọba yóó kún àwọn ẹbí olóògbé náà lọ́wọ́ bu tútù láti tu àwọn ẹbí olóògbé náà lójú.
Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkìtì tó ń sójú agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ilejemeje,Tope Ogunleye, dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà bí ó se jí gìrì sí ọ̀rọ̀ ìjínigbé tí wọ́n fi ṣàwárí Kọmíṣọ́nnà náà lójú ọjọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ ti rẹ̀,Olabode, ẹni tí àwọn kọ̀lọ̀rànsí náà fagídí gbà lálejò ọ̀sẹ̀ kan dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà, àwọn aráàlú àti àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò fún àánú Ọlọ́run lórí rẹ̀.

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

FAYEMI CONGRATULATES EX-DEPUTY GOVERNOR, ADELABU ON 70TH BIRTHDAY

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀