Kò sí lílọ- bíbọ̀ fún olùgbé Ogun, tó ń ṣiṣẹ́ l'Eko -Dapo Abiodun


Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní ojú ni alákàn fií ṣọ́rí, àti pé ogun tí yóó wọlé kó ni , ọ̀nà la tií pàdé  rẹ̀. Èyí ló díá fún bí gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun ti kéde pé kò ní i sí firi jangan lílọ bibọ̀ ọkọ̀  fún àwọn aráàlú tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ náà, ṣùgbọ́n tó ń ṣiṣẹ́ nípìńlẹ̀ Èkó.

Gómìnà sọrọ yìí ní   ìlàkalẹ̀ bi agbara òfin kónílé-ó-gbélé yóó ṣe dínkù lọ́sẹ̀ yìí, lẹ́yìn tí Ààrẹ Muhammadu Buhari pàṣẹ rẹ̀.

Nínú ìkéde náà tí Gómìnà Àbìdun fi síta lórí ayélujára fesibúùkù  lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ó sọ pé ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Karùn -ún ni òfin kónílé-ó-gbélé yóó káṣẹ ń lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ọjọ́ Ajé ni ìjọba àpapọ̀ pá á láṣẹ pé kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn, àti ìlú Àbújá.

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

FAYEMI CONGRATULATES EX-DEPUTY GOVERNOR, ADELABU ON 70TH BIRTHDAY

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀