Ìpínlẹ̀ Kano rugi oyin lọ́wọ́ Kofi 19-- Ganduje


Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ọ̀ràn kalẹ̀, kan baálé, ò lè sún kan jẹ́jẹ́ n mo jókòó ò mi o. Ìdí ní pé, bí ìròyìn tó ń jáde látọ̀dọ̀ gómìnà ìpínlẹ̀   kano, Abdullahi Ganduje bá ṣe é gbẹ́mìí lé, wàhálà ń bẹ púpọ̀ lọ́nà fún ìpínlẹ̀ náà o, látàrí àjàkálẹ̀ àrùn Kofi 19.

Gómìnà Ganduje ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta níbi ayẹyẹ ṣíṣí ibùdó àyẹ̀wò alágbèéká fún àrùn apinni léèmí coronavirus eléyìí tí ìlúmọ̀ọ́ká olókoòwò  n nì, Dangote gbé kalẹ̀ fún ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Ganduje ní ìpínlẹ̀ náà ti rugi oyin lọ́wọ́ àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún .

Ó ní ìdíwọ́ tó wáyé lórí àìtètè bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò àwọn tó lárùn náà ní ìpínlẹ̀ Kano kún ara ohun tó ṣe àkóbá fún bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ṣe ń kó àrùn náà níbẹ̀.

“Kò sí àpẹ́sọ pé ìlú Kano ti lu gúdẹ lórí ọ̀rọ̀ àrùn apinni léèmí coronavirus yìí. Kò sì sí kálọkábọ̀ kankan lórí pé bí á ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí mímójútó àrùn náà kò káre tó. Nígbà tí a bá ń kó àyẹ̀wò lọ sí Abuja, tí ó ń gba wákàtí méje lọ, wákàtí méje míràn bọ̀, kò sí àníàní pé èyí kò káre tó.”

Bákan náà, olùdarí àgbà fún àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NCDC, Dókítà Chikwe Ihekweazu ti fi ọkàn àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà balẹ̀ pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà paàpá lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì yii.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

Ekiti Governor's Lodge in Abuja: Between due process and ill-informed interference - By Segun Dipe

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu