Igbákejì Ààrẹ, alága àwọn 'kògajùgò' lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà--Nasir El-Rufai


Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí Orílẹ̀ yìí tí ń la ìṣòro àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ Kofi 19 yìí kọjá lọ́wọ́, onírúurú ìbẹ̀rù bojo ló gbọkàn àwọn ọmọ Nàìjíríà kan fún ọ̀kan ò jọ̀kan ìṣòro tí wọ́n ń là kọjá. Ṣùgbọ́n kí ìfúnpá wọ́n má tún ga jù,gómìnà ìpínlẹ̀ kan lókè ọya tí ju ọrọ apani lẹ́rìn ín kan kalẹ̀ pé ,  àìpèpàdé àwọn tí kò ga púpọ̀ ní ìdúró ni kò jẹ́ ká mọ alága àwọn tí kò jìnà sílẹ̀.

Èyí lọrọ tó jẹyọ nínú àpárá kan tí gómìnà ìpínlẹ̀ Kàdúná, Nasir El-Rufai fi ìgbákejì Ààrẹ, Yẹmi Oṣinbajọ dá pé òun ni Alága ẹgbẹ́ àwọn èèyàn tí kò ga púpọ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ní ọjọ́ Ajé ni Gómìnà El-Rufai fi ọ̀rọ̀ yìí síta lójú òpó abẹ́yefò twitter rẹ , ní ìdáhùn sí fídíò kan eléyìí tí gbajúgbajà adẹ́rìnínpòsónú n  nì, Tẹju babayface fi síta lójú òpó abẹ́yefò twitter níbi tó ti ń fi ọ̀rọ̀ wá El-Rufai lẹ́nu wò lọ́dún 2010 tí ó sì ní òun ni akọ̀wé ẹgbẹ́ àwọn èèyàn kúkúrú lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

"Bẹ́ẹ̀ ni...Mo rántí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò @Tejubabyfacetv yìí lọ́dún 2010... ọjọ́ rèé bí àná... ìgbákejì Ààrẹ Osinbajo ni Alága àwọn èèyàn kúkúrú lọ́wọ́ yìí..."

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

Fayemi Approves Ilomu, Otun Obas-Elect, Forwards Supplementary Budget to Assembly

Me, Adedubu, Alao-Akala And Obasanjo - By Rashidi Ladoja