Gbajúgbajà akọ̀ròyìn NTA àti Gáàdìan lùgbàdì Kofi 19Fẹ́mi AkínṣọláBí a bá ń sọ́ orí olórí, à fi kí á kún fún àdúrà pé kí àwòdì o má yọ́ kẹ́lẹ́ jí ti olúwarẹ̀ gbé  sálọ.Ó díá fún bí ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Katsina ti banújẹ́ lórí bi ọ̀kan lára wọn, gbajúgbajà akọ̀ròyìn n nì, Ayinde Soaga, se lùgbàdì àrùn Kofi 19, nígbà tí akọ̀wé ẹgbẹ́ akọròyìn ẹ̀ka Sókótó Meya kúkú u kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí .

Soaga tó tún jẹ́ ọ̀ga àgbà Ilé ìṣẹ amóhùnmáwòrán Nàìjíríà, NTA Katsina ni ẹgbẹ́ náà sọ nínú àtẹ̀jáde pé àyẹ̀wò fihàn pé àrùn ajániláyà pàtì ọ̀hún Covid-19, tí ta kóró wọnú àgọ́ ará rẹ.

Púpọ̀ àwọn akọ̀ròyìn ni ó wà nínú ewu àrùn apinni léèmí yìí ní Nàìjíríà nípaṣẹ̀ lílọ bíbọ̀ láti lè se àkójọpọ̀ ìròyìn fáráyé gbọ́.

Alága ẹgbẹ́ náà, Tukur Dan Alli, sọ pé àsìkò yí làwọn akọ̀ròyìn nílò ìrànwọ́ Ìjọba àti àwọn aládàáni láti le dáàbò tó péye bò wọ́n, lórí iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò.

Ó késì ìjọba àti àwọn tí ó lẹ́nu lọrọ lẹ́ka ìròyìn láti pèsè irinṣẹ́ ìdáàbòbò ẹni àti àwọn nǹkan míràn tó le kó àwọn akọ̀ròyìn yọ lọ́wọ́ àrùn ajániláyà pàtì Covid 19.

Bákan náà ní ìròyìn tí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àkọ̀wé àjọ náà Meya tí dágbére fayé.
Ọrọ yìí ni ọ̀gbẹ́ni Abubakar Awwal fí léde pé akọ̀wé ilé ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn náà ẹ̀ka ti Sòkòtò ti fayé lẹ̀ . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àyẹwò Kofi 19 tí wọ́n se fún un kò tíì jáde, síbẹ̀, àbájáde àyẹwò ọ̀hún  fihàn pé olóògbé ní àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Alága ẹgbẹ́  akọròyìn níbẹ̀,lsa Abubakar Shuni ti sàpèjúwe ikú akọ̀wé ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn náà bíi àjálù ńlá fún gbogbo akọ́sẹ́mọsẹ́  akọròyìn.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé