Ọmọ Nàìjíríà láti UK dèrò ibùdó ìyàsọ́tọ̀ fún Kofi 19
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ti kó àwọn ọmọ Nàìjíríà 253 tó padà sílé lọ́jọ́ Ẹtì láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì lọ sí ibùdó  ìyàtọ̀  aíbàámọ̀ àwọn mìíràn nínú wọn le lárùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Ìsọ̀rí kejì àwọn ọmọ Nàìjíríà tó dé láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed (MMIA), nílùú Èkó

Ṣaájú ni àwọn mìíràn ti rìnrìn àjò wálé láti Dubai lórílẹ̀-èdè United Arab Emirates (UAE)

Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò bí ara wọ́n ṣe ń gbóná sí ni wọ́n fi ọkọ̀ kó wọn lọ sí ibùdó ìyàtọ̀ tí wọ́n ti pèsè sílẹ̀ fún wọn.

Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni wọ́n tún fi bàálú gbé lọ sí ìlú Àbújá níbi tí wọn yóó ti wà ní ìgbélé fún ọjọ́ mẹ́rìnlà.

Ṣùgbọ́n àwọn kan fi àìdùnnú wọn hàn sí bí wọ́n ti gbé wọ́n lọ sí Àbújá, wọ́n ní àwọn kò lárá tàbí  ìyekan nílùú Àbújá.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé