Fáyemí fi imọrírì hàn sí bàbá tó yarí f'ọ́mọ ẹ lórí Covid 19.


Fẹ́mi Akínṣọlá


Gómìnà ìpínlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ní òun ti yan bàbá tí fọ́rán rẹ̀ tàn ká orí ayélujára lásìkò tó ń bá ọmọ rẹ̀ jà pé kò le tẹ̀lé òun lọ ilé láì ṣe àyẹ̀wò Covid-19, lẹ́yìn tó ti ìrìn àjò dé láti ìpínlẹ̀ Èkó gẹ́gẹ́ bí asojú ìjọba lórí ọ̀rọ̀  àrùn apinni léèmí Covid-19 ní ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Gómìnà fi ọ̀rọ́ yìí léde lorí àtẹ̀jiṣẹ́ twitter rẹ̀ pé, inú òun dùn fún igbésẹ ọ̀gbẹ́ni Femi Adeoye pẹ̀lú bí ó ṣe ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí rẹ̀ nítori pé ó ní ìgboyà, ó sì nífẹ̀ẹ́ ìpínlẹ̀  Èkìtì lọ́kan.

Ó ní ọ̀gbẹ́ni Adeoye yóó ran ìjọba lọ́wọ́ láti máa tan àwọn ìpolongo lórí àrun ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún, corornavirus, yóò si jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lóri ọ̀rọ̀ kòrónáfairọ̀ọ̀sì nípìnlẹ̀ Èkìtì.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé