Ẹ̀mí mẹ́rin sọnù, ọ̀pọ̀ èèyàn fara pa lópòópónà márosẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀  ló pàdánù ẹmi wọn tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn mìíràn sì fi ara pa nínú ìjàǹbá ọkọ̀ tó wáyé nílù ú Ògbómọ̀ṣọ́ lọ́sàn ọjọ́ Ẹtì.

Ní agbègbè Apake lópòópónà márosẹ̀  Ògbómọ̀ṣọ́ Ilọrin àtijọ́, ni ọkọ̀ akẹ́rù kan ti ṣá wọ ibi tí àwọn èrò ọkọ̀ àti ọlọ́kadà kórajọ sí.

Ó ṣojú mi kòró ṣe àlàyé fún àwọn oníròyìn pé èèyàn mẹ́rin ló kú lójú ẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe kó àwọn tí ó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn Òyìnbó, LAUTECHTH tó ń bẹ nílùú Ògbómọ̀ṣọ́ . Ìròyìn sọ pé ẹkùn àríwá ni ọkọ̀ náà ń rin ìrìnàjò lọ kí ó tó di wí pé ó pàdánù ìjánu ọkọ̀ lásìkò tó ń ṣá fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó nílùú Ògbómọ̀ṣọ́, ṣùgbọ́n adarí ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó tó ń bẹ ní agbègbè náà, Bọlade Olugbẹsan sọ wí pé irọ tó jìnà sí òótọ́ ni ẹ̀sùn náà.
Ó ní kò sí òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò púpọ̀ ní ibi tí ìjàmbá náà ti ṣẹlẹ̀ . Ó ṣojú mi kòró míì tí ó bá àwọn oníròyìn ṣ'ọ̀rọ̀ ṣe àlàyé pé ọlọkada ni awọn èèyàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàǹbá náà.

Lásìkò tí a ṣe àkójọpọ̀ ìròyìn yìí, àwọn òṣìṣẹ́ ààbò dúró wámúwámú sí ọ́fíísì ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó tó ń bẹ ní agbègbè 'High School' nílùú Ògbómọ̀ṣọ́ láti dènà àkọlù àwọn ará ìlú tó ń fapájánú nítorí ìjàǹbá náà.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

Ekiti Governor's Lodge in Abuja: Between due process and ill-informed interference - By Segun Dipe

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu