Ẹ wògbéwọ̀nsí àgbo Madagascar fún ìtọ́jú covid-19--- Buhari


Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní ọmọ onílùú kò ní fẹ́ kó tú. Bẹ́ẹ̀ kọ́ má bàjẹ́,kọ́ má bàjẹ́ laájò àgbà díá fún bí
aláṣẹ Orílẹ̀ yìí
Ajagun gbébọn tì Muhammadu Buhari ti pàṣẹ lílò àgbo kòrónáfairọ̀ọ̀sì láti orílẹ̀-èdè Madagascar ṣe ìtọ́jú àwọn tó lùgbàdi àrùn ní Nàìjíríà.

Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá lórí àti gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn Kofi-19 ní Nàìjíríà, Boss Mustapha ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fáwọn akọ̀ròyìn nílùú Àbújá lọ́jọ́ Ajé.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Madagascar ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àgbo náà ń dènà àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì , bákan náà ló ń wo àìsàn náà.

Ìjọba orílẹ̀-èdè náà ní òhun ti fi àgbo náà tó jẹ́ ti Nàìjíríà ránṣẹ́ sí Equitorial Guinea níbi yóó ti wọ ìlú Àbújá.

Bó tílẹ̀ jẹ́ pé akọ̀wé ìjọba kò sọ ọjọ́ kan pàtó tí wọn yóó kó àgbo náà wọ Nàìjíríà, ó ní gbogbo ètò ti tò láti lọ kó àgbo náà láti Equitorial Guinea.

Ọ̀gbẹ́ni Mustapha ní Ààrẹ Buhari pàṣẹ pé kí àwọn elétò ìlera ṣe àyẹ̀wò òògùn náà fínífíní kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní lò ó fáwọn èèyàn Orílẹ̀ yìí.

Ẹ̀wẹ̀, Mínísítà ètò ìlera, Dókítà Ehanire Osagie ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn elétò ìlera yóó ṣe àyẹ̀wò àgbo náà.

Àwọn onímọ ìjìnlẹ̀ káàkiri àgbáyé ṣì ń ṣiṣẹ́ ìwádìí láti wá òògùn tàbí abẹrẹ tó le wo àrùn apinni léèmí Kofi 19 ṣùgbọ́n kò tí ì sí òògùn àrùn náà di àkókò yìí.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

Ekiti Governor's Lodge in Abuja: Between due process and ill-informed interference - By Segun Dipe

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu