Ẹ bomú bonu, kẹ́ ẹ má jẹ pàsán òfin -- Ìjọba àpapọ̀


Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ko ko ko là á ránfá adití. Ajá tá ò bá sì fẹ́ kó sọnù, ìfè la fi í pè é.
Èyí ló mú kí Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà  ó máa ké tantan bí ó se fi àwọn òfin túntun míràn síta, lójúnà àti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹrin oṣù karùn- ún ọdún 2020.

Akòwé àgbà ìjọba àpàpọ Ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ní ẹnikẹ́ni tí kò bá lo ìbòmù ní ìgboro tàbí níbi tí èrò bá pọ̀ sí ń fi ọwọ́ pa idà òfin lójú.

Ó ní àwọn ìlànà ìjọba yìí kan gbogbo ènìyàn àti àwọn elétò ààbò .

Akọ̀wé ìjọba ní ẹnikẹ́ni tí ara rẹ̀ bá ti gbóná kọjá ìwọn méjìdínlógójì yóó padà silé lábẹ́ àkóso túlàsì, bákan náà ni wọ́n sì gbọdọ̀ pé àjọ NCDC láti wá se àyẹ̀wò.

"Ẹnikẹ́ni tó bá tàpá s'ófin lílo ìbòmú kò gbọdọ̀ wọ ilé iṣẹ́, nítorí náà, kí àwọn aṣọ́nà dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ padà sílé.

"Ẹnikẹ́ni tó bá tẹ òfin kónílé-ó-gbélé mọ́lẹ̀ lẹ́yìn wákàti tí Ìjọba là sílẹ̀, tí kìí sìí ṣe òṣìṣẹ́ tó pọndandan láti wà nígboro, tàbí tó péjọ sí ibi ayẹyẹ tó ju ogún ènìyàn lọ yóó fojú winá òfin ọba.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé