Akójàánu ilé l'Ékìtì pín nǹkan ìdẹ̀rùn ojúlé dójúlé f'áráàlù


Fẹ́mi Akínṣọlá

Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkìtì
Ọnarebu Funminiyi Afuye tí bẹ̀rẹ̀ abala kejì pínpín nǹkan ìdẹrun f'áwọn aráàlú,lójúnà àti díhò tí àrùn ajà má mààlà Kofi 19 ti dá sí wọn láa.

Nínú ìrìn àjò  ìpele kejì yìí ,tó gbéwọn yípo náà ní wọ́n tí yọjú sí àwọn èèyàn agbègbè ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀  mẹ́ta nínú un márùn ún.
Ètò ìpele kejì yìí ní a ti rí olórí òṣìsẹ́ ní ọ́fíìsì Akójàánu ilé ọ̀gbẹ́ni Alao Iyiola, tí ó léwájú yípo láti pín àwọn n tẹ́nu ún jẹ bíi ,búrẹ́dì, àpò ìrẹsì, índómì àti ohun ìbòmú 

Àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n pín nǹkan ìdẹrun dé ni Are/Araromi/Ayetoro; Afao/Kajola àti Ilapetu/Ijao nígbà tí ọwọ́jà àwọn ohun ìdẹ̀rùn tí wọ́n ń pín ọ̀hún yóó gbìnàyá lọ́jọ́ Túsìdeè  ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ dé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ méjì tó kù

Nígbà tó ń f'èsì sí ókoto ìbéèrè látẹnu akọròyìn, Olùdámọ̀ràn akójàánu ilé lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ́ mọ́ ìròyìn Akogun Tai Oguntayo mẹnuba Idemo àti  Ogbonjana bíi Wọ́ọ̀dù méjì tí èyí tó ṣẹ́kù tí yóó jàǹfàni ohun ìdẹ̀rùn náà bí adarí Ilé se piyamọ rẹ̀.

" A mọ̀ pé kò sí bí ọwọ́jà náà yóó ṣé kárí gbogbo èèyàn láti Wọ́ọ̀dù ọ̀hún, ṣùgbọ́n a wọ ilé lọ láti pín ohun ìdẹ̀rùn fún àwọn èèyàn tí kò rọ́wọ́ họrí, láì fi ti ẹgbẹ́ òsèlú tàbí ẹ̀sìn se"
Nígbà tó ń bá àwọn èèyàn ṣọ̀rọ̀, láwọn ibùdó òpópónà, olórí òṣìṣẹ́ ní ọ ọ́fíísì Adarí ilé, gba àwọn èèyàn ìlú náà láti máa pá òfin

Lára àwọn   amúgbálẹ́gbẹ̀ Adarí ilé tó jùmọ̀ jíṣẹ́ lórúkọ akójàánu ilé fún ìpínlẹ̀ Èkìtì ní a tí rí Ọ̀gbẹ́ni Stephen Olawande àti Adeola Agboola,tó fi mọ́, Folakemi Jayeola àti
Ọnarẹ́bù Dele Fituyi.

Comments

Popular posts from this blog

Ayade, The Cry Cry Baby In Peregrino House By AGBA JALINGO

FAYEMI CONGRATULATES EX-DEPUTY GOVERNOR, ADELABU ON 70TH BIRTHDAY

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀