Adarí O’odua tuntun, ifá Fáyemí mú OlujobiFẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé orí tí yóó bá dá dé, inú agogo idẹ ní tí i wá, ọrùn tí yóó lèjígbà Ìlẹ̀kẹ̀, inú agogo idẹ ní tí i wá,ibadi tí yóó lo mọ́ṣàajì aṣọ Ọba tíí tanná yanranyanran , kìí ṣẹ̀yìn inú agogo idẹ.
Ọ̀rọ̀ yìí ló díá fún bí
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọ̀mọ̀wé Káyọ̀dé Fáyemí ti buwọ́ lu ìyànsípò Olùdarí ilé iṣẹ́ (Vertex Energy Limited )  Onímọ̀ Ẹ̀rọ Yinka Oyebode láti ìpínlẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí asojú Àjọ okoòwò O'odua.

Olujobi, ọmọ bíbí ìlú Emure Ekiti jẹ́ akẹ́kọ́ọ̀jáde Christ’s School, Ado-Ekiti, àti Fásitì ìlú Èkó  níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ nínu imọ ẹ̀rọ  Mẹ̀káníkà tí ìrírí òhun ìtẹ̀síwájú imọ sì ti ṣọ ọ́ di ọ̀jìnmì onímọ nípa  ìnáwó àti ìsàkóso.

Gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn Ọ̀gbẹ́ni Yinka Oyebode ti fi léde,
 'ìrírí ọgbọ̀n ọdún tó ní láágbọn iṣẹ́ o yàn láàyò níbi tó ti dipò kàn-àn-rìn mú, láàrin ọdún 1987- 2008) àti  (2008-2010)".

Kò tàn síbẹ̀,Olujobi, tún tí fìgbàkan jẹ́ Alága àjo kan tí kìí se t'ìjọba, tí wọ́n dàpè ní( LEAP Africa, a Non-Governmental Organisation àti ọmọ ìgbìmọ̀ board ilé iṣẹ́ àdáni (First Hydrocarbon Nigeria6 Limited & Falcon Corporation) àti àwọn mìíràn.

Gbogbo àwọn omilẹgbẹ ìrírí wònyí àti òmíràn kún àwòmọ́ tó ń ṣàfíhàn pé onímọ̀ ẹ̀rọ náà yóó yanyọ ní ààyè tuntun yìí.

 Olujobi ní ìyàwó bẹ́ẹ̀ ló Èdùwà fi ọmọ jíǹkì  ẹ̀.

Comments

Popular posts from this blog

Ekiti: Governor Responds To Claims Of Selling State Lodge ln Abuja

"President Buhari Trusts Women More Than Men" - Garba Shehu

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé